Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 4:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Jésù sì dahùn ó wí fún un pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

13. Nígbà tí Èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ di sáà kan.

14. Jésù sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Gálílì: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.

15. Ó sì ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.

16. Ó sì wá sí Násárẹ́tì, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú sínágọ́gù lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé.

17. A sì fi ìwé wòlíì Àìsáyà fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:

18. “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,Nítorí tí ó fi àmì òróró yàn míláti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòsì.Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àtiìtúnríran fún àwọn afọ́jú,àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,

Ka pipe ipin Lúùkù 4