Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 3:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹẹ̀dógún ìjọba Tiberíù Késárì, nígbà tí Pontíù Pílátù jẹ́ Baálẹ̀ Jùdéà, tí Hẹ́ródù sì jẹ́ tẹ́tírákì Gálílì, Fílípì arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetírákì Ituréà àti ti Tirakonítì, Nísáníà sì jẹ́ Tétírákì Ábílénì,

2. Tí Ánásì òun Káíáfà ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọ Sakaráyà wá ní ijù.

3. Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ ìha Jọ́dánì, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀;

4. Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà pé,“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,Ẹ mú ipa-ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

5. Gbogbo ọ̀gbun ni a óò kún,Gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ̀bẹ̀rẹ̀;Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,àti ọ̀nà gbọ́ngun-gbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.

6. Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

7. Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?

8. Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwá ní Ábúráhámù ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Ábúráhámù nínú òkúta wọ̀nyí.

9. Àti nísinsìnyí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a ké e lulẹ̀, a sì wọ́ ọ jù sínú iná.”

Ka pipe ipin Lúùkù 3