Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 3:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹẹ̀dógún ìjọba Tiberíù Késárì, nígbà tí Pontíù Pílátù jẹ́ Baálẹ̀ Jùdéà, tí Hẹ́ródù sì jẹ́ tẹ́tírákì Gálílì, Fílípì arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetírákì Ituréà àti ti Tirakonítì, Nísáníà sì jẹ́ Tétírákì Ábílénì,

2. Tí Ánásì òun Káíáfà ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọ Sakaráyà wá ní ijù.

3. Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ ìha Jọ́dánì, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀;

Ka pipe ipin Lúùkù 3