Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 21:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

7. Wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti àmì kíní yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”

8. Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má báà mú yín sìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kírísítì náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”

10. Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba.

11. Ilẹ̀ríri ilẹ̀ ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.

Ka pipe ipin Lúùkù 21