Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 2:39-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Gálílì, sí Násárẹ́tì ìlú wọn.

40. Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.

41. Àwọn òbi rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerúsálémù ní ọdọọdún sí Àjọ-ìrékọjá.

42. Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerúsálémù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà.

43. Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jésù dúró lẹ́yìn ní Jerúsálémù; Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀.

44. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn.

45. Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerúsálémù, wọ́n ń wá a kiri.

46. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹ́ḿpílì ó jòkòó ní àárin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ti wọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè.

47. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀.

48. Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, bàbá rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbìnújẹ́ wá ọ kiri.”

49. Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”

50. Ọ̀rọ̀ tí sọ kò sì yé wọn.

51. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Násárétì, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 2