Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 19:39-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Àwọn kan nínú àwọn Farisí nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”

40. Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”

41. Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí,

42. Ó ń wí pé, “Ìbáṣepé ìwọ mọ̀, lóní yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlààáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ.

43. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo.

44. Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”

45. Ó sì wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde;

46. Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò olè.”

47. Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹ́ḿpìlì, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á run.

48. Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 19