Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 17:23-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìnín;’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má se tẹ̀lé wọn.

24. Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apákan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀.

25. Ṣùgbọ́n kò lè sàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.

26. “Bí ó ti rí ní ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ ọmọ ènìyàn.

27. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Nóà wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.

28. “Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọ́ọ̀tì; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé;

29. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Ṣódómù, òjò iná àti súfúrù rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.

30. “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí ọmọ ènìyàn yóò farahàn.

31. Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má se sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn.

32. Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.

33. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là.

34. Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.

35. Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 17