Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 16:25-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. “Ṣùgbọ́n Ábúráhámù wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lásárù ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

26. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má baa le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’

27. “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán an lọ sí ilé baba mi:

28. Nítorí mo ní arákùnrin márùnún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má baa wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’

29. “Ábúráhámù sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mósè àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ ti wọn.’

30. “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ábúráhámù baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’

31. “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mósè àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”

Ka pipe ipin Lúùkù 16