Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 16:16-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Jòhánù: Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí sóńsó kan ti òfin kí ó yẹ̀.

18. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.

19. “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ asọ elésèé àlùkò àti asọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójóojúmọ́:

20. Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lásárù, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju,

21. Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.

22. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn ańgẹ́lì gbé e lọ sí oókan-àyà Ábúráhámù: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;

23. Ní ipò-òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìṣẹ́ oró, ó sì rí Ábúráhámù ní òkèrè, àti Lásárù ní oókan-àyà rẹ̀.

24. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Ábúráhámù, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lásárù, kí ó tẹ oríka rẹ̀ bọmi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

25. “Ṣùgbọ́n Ábúráhámù wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lásárù ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

26. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má baa le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’

Ka pipe ipin Lúùkù 16