Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 14:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbé ga.”

12. Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá se àṣè ọ̀sán má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà.

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkù àrùn, àwọn amúkún-ún, àti àwọn afọ́jú:

14. Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítori wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòótọ́.”

15. Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jésù pé, “Alábúkùn ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ ase ní ìjọba Ọlọ́run!”

16. Jésù dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan se àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀.

17. Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣe tán!’

18. “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ ní ohùn kan láti ṣe àwáwí. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

19. “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

20. “Ẹ̀kẹ́ta sì wí pé, ‘Mo sẹ̀sẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’

21. “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpòpò ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúkùn-ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’

22. “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, àyè sì ń bẹ síbẹ̀.’

Ka pipe ipin Lúùkù 14