Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 14:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisí lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ.

2. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí ó ní àsunkún ń bẹ níwájú rẹ̀.

3. Jésù sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisí pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbi kò tọ́?”

4. Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó sì mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.

5. Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?”

6. Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.

7. Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé:

8. “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.

9. Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ àti òun bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní àyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn.

10. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó t'oúnjẹ.

11. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbé ga.”

12. Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá se àṣè ọ̀sán má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà.

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkù àrùn, àwọn amúkún-ún, àti àwọn afọ́jú:

Ka pipe ipin Lúùkù 14