Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 12:23-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ọkàn sáà ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ.

24. Ẹ kíyèsí àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sáà ń bọ́ wọn: mélòómélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ!

25. Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ìgbé ayé rẹ̀?

26. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹyin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?

27. “Ẹ kíyèsí àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́sọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí.

28. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko ìgbẹ́ ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónì-ín, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòómélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin oní kékeré ìgbàgbọ́.

29. Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣàníyàn ọkàn.

30. Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀ èdè ayé lé kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ nǹkan wọ̀nyí.

31. Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.

32. “Má bẹ̀rù, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín.

33. Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́.

34. Nítorí ní ibi tí ìṣura yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.

35. “Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó.

36. Kí ẹ̀yin tìkárayín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé: pé, nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán.

37. Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń sọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

38. Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ náà.

39. Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, (òun ìbá máa ṣọ́nà) kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun.

40. Nítorí náà kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú: Nítorí ọmọ ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.”

Ka pipe ipin Lúùkù 12