Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 12:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”

13. Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”

14. Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, tani ó fi mí jẹ onídájọ́ tàbí olùpí-ogúnn fún yín?”

15. Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì má a sọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”

16. Ó sì pa òwe kan fún wọn, pé, ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso:

17. Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.”

18. Ó sì wí pé, “Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èṣo àti ọrọ̀ mi jọ sí.

19. Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, má a yọ̀.”

20. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, “Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó bèèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti tani nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?”

21. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìsúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

22. sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣàníyàn nítorí ọkàn yín pé, kínni ẹ̀yin ó fi bora.

23. Ọkàn sáà ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ.

24. Ẹ kíyèsí àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sáà ń bọ́ wọn: mélòómélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ!

25. Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ìgbé ayé rẹ̀?

Ka pipe ipin Lúùkù 12