Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 12:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọ pọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa sọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisí tí í ṣe àgàbàgebè

2. Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀.

3. Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní ìkọ̀kọ̀, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.

4. “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́.

5. Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpádì: lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.

6. Ológoṣẹ́ márùn ún sáà ni a ń tà lówó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run?

7. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológóṣẹ́ púpọ̀ lọ.

8. “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run:

Ka pipe ipin Lúùkù 12