Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 11:42-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisí, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá mítì àti rue, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsì fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.

43. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisí, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú sínágọ́gù, àti ìkíni ní ọjà.

44. “Ègbé ni fún-un yín, (ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisí àgàbàgebè) nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”

45. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.”

46. Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkarayín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà.

47. “Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa.

48. Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn.

49. Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì se wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn àpósítélì sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’

50. Kí a lè bèèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí;

51. Láti ẹ̀jẹ̀ Ábélì wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sakaráyà, tí ó ṣègbé láàrin pẹpẹ àti tẹ́ḿpìlì: lóòótọ́ ni mo wí fún yín.

52. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.”

53. Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀.

54. Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú mọ́ ọn lẹ́nu kí wọn báà lè fi ẹ̀sùn kàn án.

Ka pipe ipin Lúùkù 11