Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 11:29-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí: wọ́n ń wá àmì; a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jónà wòlíì!

30. Nítorí bí Jónà ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Nínéfè, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí.

31. Ọba-bìnrin gúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì: sì kíyèsí i, ẹni tí ó pọ̀ju Sólómónì lọ ń bẹ níhín-ín yìí.

32. Àwọn ará Nínéfè yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jónà; sì kíyèsíi, ẹni tí ó pọ̀jù Jónà lọ ń bẹ níhín-ín yìí.

33. “Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí i gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé baà lè má a rí ìmọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 11