Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 1:72-76 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

72. Láti ṣe àánú tí ó ti lérí fún àwọn baba wa,Àti láti rántí májẹ̀mu rẹ̀ mímọ́,

73. ìbúra tí ó ti bú fún Ábúráhámù baba wa,

74. láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,Kí àwa kí ó lè máa sìn ín láìfòyà,

75. Ní mímọ́ ìwà àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.

76. “Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:Nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;

Ka pipe ipin Lúùkù 1