Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kólósè 3:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nítorí ẹ̀yín ti kú, a sì fi iyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kírísítì nínú Ọlọ́run.

4. Nígbà tí Kírísítì, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.

5. Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyìí jásí ìbọ̀rìsà.

6. Lórí àwọn wọ̀nyìí ni ìbínú Ọlọ́run ńbọ̀ wá.

7. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apákan ayé yìí.

8. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyìí sílẹ̀: ìbínú, ìrúnú, àránkan, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín.

9. Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ayé yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀,

10. tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé titun wọ̀, èyí tí a sọ di titun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dáa.

11. Níbi tí kò gbé sí Gíríkì tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìnímọ̀, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kírísítì ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

12. Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìsoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù.

13. Ẹ máa fara dàá fún ara yín, ẹ sì máa dáríji ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kírísítì ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Kólósè 3