Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kólósè 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. íwọ̀n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kírísítì ẹ máa ṣafẹrí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kírísítì gbé wà tí ó jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.

2. Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lóké kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé.

3. Nítorí ẹ̀yín ti kú, a sì fi iyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kírísítì nínú Ọlọ́run.

4. Nígbà tí Kírísítì, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.

5. Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyìí jásí ìbọ̀rìsà.

Ka pipe ipin Kólósè 3