Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 9:27-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ó dá wọn lóhùn wí pé, “Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́: nítorí kínni, ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́? Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí?”

28. Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yin rẹ̀: ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mósè ni àwa.

29. Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eleyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”

30. Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sáà ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n Òun sáà ti là mí lójú.

31. Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.

32. Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.

33. Ìbáṣepé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.”

34. Sí èyí, wọ́n fèsì pé: “Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí?” Wọ́n sì tì í sóde.

35. Jésù gbọ́ pé, wọ́n ti tì í sóde; nígbà tí ó sì rí i, ó wí pe, “Ìwọ gba Ọmọ Ọlọ́run, gbọ́ bí?”

36. Òun sì dáhùn wí pé, “Ta ni, Olúwa, kí èmi lè gbà á gbọ́?”

37. Jésù wí fún un pé, “Ìwọ ti rí i, Òun náà sì ni ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.”

38. Ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́,” ó sì wólẹ̀ fún un.

39. Jésù sì wí pé, “Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran; àti kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”

40. Nínú àwọn Farisí tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú fọ́jú bí?”

41. Jésù wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran’, nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 9