26. Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé, “Kí ni ó ṣe ọ́? Báwo ni ó ṣe là ọ́ lójú.”
27. Ó dá wọn lóhùn wí pé, “Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́: nítorí kínni, ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́? Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí?”
28. Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yin rẹ̀: ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mósè ni àwa.
29. Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eleyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”
30. Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sáà ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n Òun sáà ti là mí lójú.
31. Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.
32. Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.
33. Ìbáṣepé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.”
34. Sí èyí, wọ́n fèsì pé: “Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí?” Wọ́n sì tì í sóde.
35. Jésù gbọ́ pé, wọ́n ti tì í sóde; nígbà tí ó sì rí i, ó wí pe, “Ìwọ gba Ọmọ Ọlọ́run, gbọ́ bí?”
36. Òun sì dáhùn wí pé, “Ta ni, Olúwa, kí èmi lè gbà á gbọ́?”
37. Jésù wí fún un pé, “Ìwọ ti rí i, Òun náà sì ni ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.”
38. Ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́,” ó sì wólẹ̀ fún un.
39. Jésù sì wí pé, “Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran; àti kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”