Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 9:20-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú:

21. Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀; ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀: ẹni tí ó ti dàgbà ni Òun; ẹ bi í léèrè: yóò wí fúnra rẹ̀.”

22. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn sọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kírísítì ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sínágọ́gù.

23. Nítorí èyí ni àwọn òbí rẹ̀ fi wí pé, “Ẹni tí ó dàgbà ni Òun, ẹ bi í léèrè.”

24. Nítorí náà, wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ògo fún Ọlọ́run: àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí jẹ́.”

25. Nítorí náà, ó dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, èmi kò mọ̀: Ohun kan ni mo mọ̀, pé mo tí fọ́jú rí, nísinsin yìí mo ríran.”

26. Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé, “Kí ni ó ṣe ọ́? Báwo ni ó ṣe là ọ́ lójú.”

27. Ó dá wọn lóhùn wí pé, “Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́: nítorí kínni, ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́? Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí?”

28. Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yin rẹ̀: ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mósè ni àwa.

29. Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eleyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”

30. Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sáà ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n Òun sáà ti là mí lójú.

Ka pipe ipin Jòhánù 9