Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 7:49-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”

50. Nikodémù ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé,

51. “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

52. Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Gálílì bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Gálílì dìde.”

53. Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 7