Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 7:10-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀.

11. Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”

12. Kíkùn púpọ̀ sì wà láàárin àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀: nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere níí ṣe.”Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.”

13. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.

14. Nígbà tí àjọ dé àárin; Jésù gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ó sì ń kọ́ni.

15. Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”

16. Jésù dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi.

17. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bíí bá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi.

18. Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòótọ́, kò sì sí àìsòdodo nínú rẹ̀.

19. Mósè kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

20. Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èsù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”

21. Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ àmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín.

22. Síbẹ̀, nítorí pé Mósè fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ mósè bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi.

23. Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mósè, ẹ ha ti ṣe ń bínú sími, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ṣáṣá ní ọjọ́ ìsinmi?

24. Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa se ìdájọ́ òdodo.”

25. Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jérúsálẹ́mù wí pé, “Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí?

Ka pipe ipin Jòhánù 7