Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 7:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jésù ńrìn ní Gálílì: nítorí tí kò fẹ́ẹ́ rìn ní Jùdéà, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa.

2. Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan.

3. Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhín-ínyìí, kí o sì lọ sí Jùdéà, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fí iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé.

4. Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkáarẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.”

5. Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbàágbọ́.

6. Nítorí náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Àkókò gan-an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín.

7. Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú.

8. Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.”

9. Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Gálílì síbẹ̀.

10. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀.

11. Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”

12. Kíkùn púpọ̀ sì wà láàárin àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀: nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere níí ṣe.”Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.”

13. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.

14. Nígbà tí àjọ dé àárin; Jésù gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ó sì ń kọ́ni.

Ka pipe ipin Jòhánù 7