Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 6:25-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apákejì òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rábì, nígbà wo ni ìwọ wá síhín yìí?”

26. Jésù dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́-àmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà.

27. Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ńṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí ọmọ-ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”

28. Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Kín ni àwa ó ha ṣe, kí a lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run?”

29. Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni iṣe Ọlọ́run pé, kí ẹ̀yin gba ẹni tí ó rán an gbọ́.”

30. Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Iṣẹ́ àmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ kínni ìwọ ṣe?

31. Àwọn baba wa jẹ mánà ní ihà; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fi oúnjẹ láti ọ̀run wá oúnjẹ fún wọn jẹ.’ ”

32. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kì í ṣe Mósè ni ó fi oúnjẹ fún yín láti ọ̀run wá; ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fi oúnjẹ òtítọ́ náà fún yín láti ọ̀run wá.

33. Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé.”

34. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.”

35. Jésù wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.

Ka pipe ipin Jòhánù 6