Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù kọjá sí apákejì òkun Gálílì, tí í ṣe òkun Tiberíà.

2. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.

3. Jésù sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀.

4. Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì sún mọ́ etílé.

5. Ǹjẹ́ bí Jésù ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílípì pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?”

6. Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.

7. Fílípì dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ níí rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

Ka pipe ipin Jòhánù 6