Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 5:37-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Àti Baba tìkárarẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀.

38. Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́.

39. Ẹ̀yin ń wá ìwé-mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rí mi.

40. Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin baà lè ní ìyè.

41. “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn.

42. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnra yín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín.

43. Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà.

44. Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?

45. “Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba: ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mósè, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lẹ́.

46. Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mósè gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́: nítorí ó kọ ìwé nípa tẹ̀mi.

47. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”

Ka pipe ipin Jòhánù 5