Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 5:28-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀.

29. Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́.

30. “Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò se ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

31. “Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́.

32. Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹrí mi tí ó jẹ́.

33. “Ẹ̀yin ti ránsẹ́ lọ sọ́dọ̀ Jòhánù, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.

34. Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ̀rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là.

35. Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sáà kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

36. “Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀ju ti Jòhánù lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rí mi pé, Baba ni ó rán mi.

37. Àti Baba tìkárarẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀.

38. Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́.

39. Ẹ̀yin ń wá ìwé-mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rí mi.

40. Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin baà lè ní ìyè.

41. “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn.

42. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnra yín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín.

Ka pipe ipin Jòhánù 5