Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 4:8-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. (Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra ońjẹ.)

9. Obìnrin ará Samáríà náà sọ fún un pé, “Júù ni ẹ́ obìnrin ará Samáríà ni èmi. Eéti rí tí ìwọ ń bèèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaríà ṣe pọ̀.)

10. Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbáṣepé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, fún mi mu, ìwọ ìbá sì ti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, Òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

11. Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní nǹkan tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jìn: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà?

12. Ìwọ pọ̀ ju Jákọ́bù baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí Òun tìkararẹ̀ mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran rẹ̀?”

13. Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òrùngbẹ yóò tún gbẹ ẹ́:

14. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fí fún un, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun títí ayérayé.”

15. Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ kí ó má se gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá máa pọn omi níbí.”

16. Jésù wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

17. Òbìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ. Jésù wí fún un pé, Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ:

18. Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní bá yìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

19. Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe.

20. Àwọn bàbá wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jérúsálẹ́mù ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

21. Jésù wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò se lórí òke yìí tàbí ní Jérúsálẹ́mù ni ẹ̀yin ó máa sin Baba.

22. Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá.

23. Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìn yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.

24. Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25. Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Mèsáyà ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Krísítì: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

26. Jésù sọ ọ́ di mímọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

27. Lórí èyí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan tí ó wí pé, “Kíni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”

28. Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé,

Ka pipe ipin Jòhánù 4