Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 4:31-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Láàárin èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Olùkọ́, jẹun.”

32. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní ońjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

33. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-èyìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnì kan mú ońjẹ fún un wá láti jẹ bí?”

34. Jésù wí fún wọn pé, “Ońjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.

35. Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkọ́rè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ sí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè.

36. Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, kódà báyìí, ó ń kórè fún ayérayé: kí ẹni tí ó ń fúrúgìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀.

37. Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnì kan ni ó fúrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ.

38. Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”

39. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.”

40. Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ijọ́ méjì.

41. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 4