Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 21:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí òkun Tíbéríà; báyìí ni ó sì farahàn.

2. Símónì Pétérù, àti Tọ́másì tí a ń pè ní Dídímù, àti Nátanáẹ́lì ará Kánà ti Gálílì, àti àwọn ọmọ Sébédè, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀.

3. Símónì Pétérù wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

Ka pipe ipin Jòhánù 21