Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 20:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀.

6. Nígbà náà ni Símónì Pétérù tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀.

7. Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n o ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀.

8. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i ó sì gbàgbọ́.

9. (Nítorí tí wọn kò sáà tí mọ ìwé mímọ́ pé, òun ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.)

10. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.

11. Ṣùgbọ́n Màríà dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń ṣọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì.

12. Ó sì kíyèsí àwọn áńgẹ́lì méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jésù gbé ti sùn sí.

Ka pipe ipin Jòhánù 20