Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 20:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà náà ni ó wí fún Tọ́másì pé, “Mú ìka rẹ wá níhín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

28. Tọ́másì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”

29. Jésù wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́: alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!”

30. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jésù ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí:

31. Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jésù ní í ṣe Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 20