Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 20:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Símónì Pétérù wá, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

3. Nígbà náà ni Pétérù jáde, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, wọ́n sì wá sí ibojì.

4. Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn sì sáré ya Pétérù, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì.

5. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀.

6. Nígbà náà ni Símónì Pétérù tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀.

7. Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n o ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀.

8. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i ó sì gbàgbọ́.

9. (Nítorí tí wọn kò sáà tí mọ ìwé mímọ́ pé, òun ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.)

10. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.

Ka pipe ipin Jòhánù 20