Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 20:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ó sì kíyèsí àwọn áńgẹ́lì méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jésù gbé ti sùn sí.

13. Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

14. Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jésù dúró, kò sì mọ̀ pé Jésù ni.

15. Jésù wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”Òun ṣebí olùsọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn yìí, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi ó sì gbé e kúrò.”

16. Jésù wí fún un pé, “Màríà!”Ó sì yípadà, ó wí fún un pé, “Rábónì!” (èyí tí ó jẹ́ Olùkọ́)

17. Jésù wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tíì gókè lọ sọ́dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”

18. Màríà Magídalénè wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.

19. Lọ́jọ́ kan náà, lọ́jọ́ kínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jésù dé, ó dúró láàárin, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”

20. Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.

21. Nítorí náà, Jésù sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.”

22. Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́!

23. Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dá dúró, a dá wọn dúró.”

24. Ṣùgbọ́n Tómásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Dídímù, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jésù dé.

Ka pipe ipin Jòhánù 20