Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 20:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kínní ọ̀ṣẹ̀ kùtùkùtù nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́ ni Màríà Magídalénè wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì.

2. Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Símónì Pétérù wá, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

3. Nígbà náà ni Pétérù jáde, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, wọ́n sì wá sí ibojì.

4. Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn sì sáré ya Pétérù, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì.

5. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀.

6. Nígbà náà ni Símónì Pétérù tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 20