Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 2:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ lè fi hàn wá, tí ìwọ fi ń se nǹkan wọ̀nyí?”

19. Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹ́ḿpílì yìí palẹ̀, Èmi ó sì tun un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

20. Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìndíláàdọ́ta ni a fi kọ́ tẹ́ḿpílì yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ijọ́ mẹ́ta?”

21. Ṣùgbọ́n Òun ń sọ ti tẹ́ḿpílì ara rẹ̀.

22. Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jésù ti sọ gbọ́.

23. Nígbà tí ó sì wà ní Jérúsálẹ́mù, ní àjọ-ìrékọjá, lákókò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì tí ó ṣe.

24. Ṣùgbọ́n Jésù kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn.

25. Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn: nítorí tí Ó mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.

Ka pipe ipin Jòhánù 2