Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 19:11-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Jésù dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò se pé a fi í fún ọ láti òkè wá: nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ jù.”

12. Nítorí èyí Pílátù ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í se ọ̀rẹ́ Késárì: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀ òdì sí Késárì.”

13. Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jésù jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Hébérù, Gábátà.

14. Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ-ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà:Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”

15. Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.”Pílátù wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?”Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kábíyèsí.”

16. Nítorí náà ni ó fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.

17. Nítorí náà, wọ́n mú Jésù, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnra rẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Hébérù tí à ń pè ní Gọlígọtà:

18. Níbití wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jésù sì wà láàárin.

19. Pílátù sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi í lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, JÉSÙ TI NÁSÁRẸ́TÌ ỌBA ÀWỌN JÚÙ.

20. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí: nítorí ibi tí a gbé kan Jésù mọ́ àgbélébùú sún mọ́ etí ìlú: a sì kọ ọ́ ní èdè Hébérù àti Látìnì, àti ti Gíríkì.

21. Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pílátù pé, “Má ṣe kọ, ‘Ọba àwọn Júù;’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni Ọba àwọn Júù.”

22. Pílátù dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.

23. Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun, nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apákan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúrán, wọ́n hun ún láti òkè títí jáde.

24. Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé-mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,“Wọ́n pín aṣọ mi láàárin ara wọn,wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ogun ṣe.

Ka pipe ipin Jòhánù 19