Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 19:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà ni Pílátù mú Jésù, ó sì nà án.

2. Àwọn ọmọ ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elésèé àlùkò wọ̀ ọ́.

3. Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú.

4. Pílátù sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.”

5. Nítorí náà Jésù jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elésèé àlùkò. Pílátù sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà!

6. Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú.”Pílátù wí fún wọn pé, “Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú: nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.”

7. Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, “Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe.”

8. Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.

Ka pipe ipin Jòhánù 19