Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 18:26-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Pétérù gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?”

27. Pétérù tún ṣẹ́: lójú kan náà àkùkọ sì kọ.

28. Nígbà náà, wọ́n fa Jésù láti ọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́: ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkara wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá.

29. Nítorí náà Pílátù jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá sí ọkùnrin yìí?”

30. Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”

31. Nítorí náà Pílátù wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”

32. Kí ọ̀rọ̀ Jésù ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.

33. Nítorí náà Pílátù tún wọ inú gbọ̀ngàn, ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jésù, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ há ni a ni Ọba àwọn Júù bí?”

34. Jésù dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”

35. Pílátù dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́: kín ní ìwọ ṣe?”

36. Jésù dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí: ìbáṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má baà fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”

Ka pipe ipin Jòhánù 18