Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 18:2-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Júdásì, ẹni tí ó dà á, sì mọ ibẹ̀ pẹ̀lú: nítorí nígbà púpọ̀ ni Jésù máa ń lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

3. Nígbà náà ni Júdásì, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà.

4. Nítorí náà bí Jésù ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni ẹ ń wá?”

5. Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jésù ti Násárétì.”Jésù sì wí fún wọn pé, “Èmi nìyí.” (Àti Júdásì ọ̀dàlẹ̀, dúró pẹ̀lú wọn.)

6. Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí, wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.”

7. Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, “Ta ni ẹ ń wá?”Wọ́n sì wí pé, “Jésù ti Násárétì.”

8. Jésù dáhùn pé, “Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí: ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ:

9. Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn.”

10. Nígbà náà ni Símónì Pétérù ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà amá a jẹ́ Mákọ́ọ̀sì.

11. Nítorí náà Jésù wí fún Pétérù pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ: ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”

12. Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀sọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jésù, wọ́n sì dè é.

13. Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Ánnà; nítorí òun ni àna Káyáfà, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà.

14. Káyáfà sáà ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfàní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.

15. Símónì Pétérù sì ń tọ Jésù lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jésù wọ ààfin olórí àlùfáà lọ.

16. Ṣùgbọ́n Pétérù dúró ní ẹnu ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùsọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé.

17. Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà wí fún Pétérù pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”Ó wí pé, “Èmi kọ́.”

Ka pipe ipin Jòhánù 18