Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 18:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Káyáfà sáà ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfàní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.

15. Símónì Pétérù sì ń tọ Jésù lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jésù wọ ààfin olórí àlùfáà lọ.

16. Ṣùgbọ́n Pétérù dúró ní ẹnu ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùsọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé.

17. Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà wí fún Pétérù pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”Ó wí pé, “Èmi kọ́.”

18. Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn alaṣẹ́ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Pétérù sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.

19. Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jésù léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

20. Jésù dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù, àti ní Tẹ́ḿpìlì níbi tí gbogbo àwọn Júù ń pé jọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀.

21. Èé ṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”

22. Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn alasẹ́ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jésù, pé, “Olórí àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”

23. Jésù dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà: ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èé ṣe tí ìwọ fi ń lù mí?”

24. Nítorí Ánnà rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Káyáfà olórí àlùfáà.

Ka pipe ipin Jòhánù 18