Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 16:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’

6. Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín.

7. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ńsọ fún yín; àǹfàní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.

8. Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráíyé níti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti níti ìdájọ́:

9. Ní ti ẹ̀ṣẹ, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́;

10. Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí;

11. Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ aládé ayé yìí.

12. “Mo ní ohun pípọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsìn yìí.

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ: yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín.

14. Òun ó máa yìn mí lógo: nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín.

15. Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni: nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín.

16. “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”

17. Nítorí náà òmíràn nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kí ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?”

Ka pipe ipin Jòhánù 16