Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 16:26-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó bèèrè lọ́wọ́ Baba fún yín:

27. Nítorí tí Baba tìkara rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá.

28. Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé: ẹ̀wẹ̀, mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”

29. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe.

30. Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”

31. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí?

32. Kíyèsí i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.

33. “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

Ka pipe ipin Jòhánù 16