Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 14:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé.

26. Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.

27. Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, Èmi ń lọ, èmi fi fún yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.

Ka pipe ipin Jòhánù 14