Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 13:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù, òun sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi?”

7. Jésù dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.”

8. Pétérù wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ mí ní ẹṣẹ̀.” Jésù sì da lóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.”

9. Símónì Pétérù wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹṣẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”

10. Jésù wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a san ẹṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.”

11. Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn; nítorí náà ni ó se wí pé, Kìí ṣe gbogbo yín ni ó mọ́

Ka pipe ipin Jòhánù 13