Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 13:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ: èmi mọ àwọn tí mo yàn: ṣùgbọ́n kí ìwé-mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’

19. “Láti ìsinsìn yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni.

20. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, ó gbà mí; Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi.”

21. Nígbà tí Jésù ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”

22. Àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ ń wò ara wọn lójú, wọ́n ń siyè méjì ti ẹni tí ó wí.

23. Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jésù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jésù fẹ́ràn.

24. Nítorí náà ni Símónì Pétérù sàpẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, “Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ.”

25. Ẹni tí ó sún mọ àya rẹ̀ bí i léèrè wí pé, Olúwa, taa ni í se?

26. Nítorí náà Jésù dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Júdásì Ísíkárótù ọmọ Símónì.

27. Ní kété tí Júdásì gba àkàrà náà ni Sátanì wọ inú rẹ̀ lọ.Nítorí náà Jésù wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń se nì, yára ṣe é kánkán.”

28. Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un.

29. Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nitorí Júdásì ni ó ni àpò, ni Jésù fi wí fún un pé, Ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn talákà.

30. Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà: òru sì ni.

31. Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jésù wí pé, “Nísinsìn yìí ni a yin ọmọ-ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 13