Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 13:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jésù mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.

2. Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Júdásì Isíkáríótù ọmọ Símónì láti fi í hàn;

3. Tí Jésù sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run;

4. Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apákan; nígbà tí ó sì mú asọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè.

5. Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwòkòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹṣẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.

6. Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù, òun sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi?”

7. Jésù dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.”

Ka pipe ipin Jòhánù 13