Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 12:27-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. “Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kínni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyì ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí.

28. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!”Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!”

29. Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, àrá ń sán: àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ańgẹ́lì kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”

30. Jésù sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín.

31. Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde.

32. Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi!”

33. Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣàpẹrẹ irú ikú tí òun ó kú.

34. Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kírísítì wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?”

35. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàárin yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín: ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun gbé ń lọ.

36. Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jésù sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn.

37. Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́.

38. Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Ìsàíàh lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé:“Olúwa, tani ó gba ìwàásù wa gbọ́Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

39. Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Ìsáyà sì tún sọ pé:

40. “Ó ti fọ́ wọn lójú,Ó sì ti sé àyà wọn le;Kí wọn má baà fi ojú wọn rí,Kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,Kí wọn má baà yípadà, kí wọn má baà mú wọn láradá.”

41. Nǹkan wọ̀nyí ni Ìsáyà wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

42. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sínágọ́gù:

Ka pipe ipin Jòhánù 12